Anglican Hymnal
Let us give praises to our God
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 550: Let us give praises to our God
E je k’a yin Olorun wa
Hymn:
550
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Iyin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ẹ jẹ k’a yìn Ọlọrun wa,
Ẹnit’ ‘O wà l’oke ọrun,
T’ O fi onjẹ fun enia,
Ti O si fi fun ẹranko.
O si tẹ oju ọrun lọ,
O da orùn on oṣupa;
Iṣẹ ọwọ Rẹ̀ n’ irawọ,
Iye wọn awa ko lè kà.
O si dá ara enia,
O si fun wọn l’ẹmi pẹlu;
O si da ni daradara,
Bi o ti yẹ, bi ‘ba ti wà.
p
Ṣugbọn enia dibajẹ,
Nwọn si bọ́ s’inu buburu
Ere ẹ́ṣẹ ni nwọn si njẹ,
pp
Ni wahala ati n’ ikú.
f
Ṣugbọn jẹ k’a yìn Ọlọrun,
On fun wa ni Kristi Jesu:
Lati wá awọn t’o ti nù,
Ninu ẹ̀ṣẹ ti nwọn ti nrin. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites