Anglican Hymnal
The Lord is coming world trembles
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 55: The Lord is coming world trembles
Oluwa mbo; aiye o mi
Hymn:
55
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Bibo Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Oluwa, mbọ̀; aiye o mì,
Oke y’o ṣidi n’ ipo wọn;
At’ irawọ oju ọrun,
Y’o mu imọlẹ wọn kuro.
f
Oluwa mbọ̀; bakanna kọ
p
Bi o ti wá n’ irẹlẹ ri;
Ọdọ-agutan ti a pa,
pp
Ẹni-iyà ti o si kú.
f
Oluwa mbọ̀, li ẹ̀ru nla,
L’ ọwọ ina pẹlu ìja
L’ or’ iyẹ apa Kerubu,
Mbọ, Onidajọ araiye.
mf
Eyi ha li ẹniti nrìn,
Bi erò l’ opopo aiye?
Ti a ṣe ‘nunibibi si?
pp
A! Ẹniti a pa l’eyi?
mf
Ika; b’ẹ wọ̀ ‘nu apata,
B’ ẹ wọ̀ nu iho, lasan ni;
f
Ṣugbọn igbagbọ t’o ṣẹgun,
ff
Y’ o kọrin pe, Oluwa de. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites