Anglican Hymnal
We love the place, O God
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 527: We love the place, O God
Olorun, awa fe
Hymn:
527
Meter:
6.6.6.6
Season:
Saju Adura
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọlọrun, awa fẹ
Ile t’ọla Rẹ wà;
Ayọ̀ ibugbe Rẹ
Ju gbogbo ayọ̀ lọ.
mf
Ile adurà ni,
Fun awa ọmọ Rẹ;
Jesu, O wà nibẹ̀,
Lati gbọ ẹbẹ wa.
Awa fẹ àse Rẹ,
Kil’ o dùn to l’aiye;
Nib’ awọn olotọ,
Nri Ọ nitosi wọn.
Awa fẹ ọ̀rọ Rẹ,
Ọrọ Alafia;
T’itunu at’ ìye,
Ọrọ ayọ titi.
f
A fẹ kọrin anú,
T’a nri gbà l’aiye yi;
cr
Ṣugbọn awa fẹ mọ̀
Orin ayọ̀ t’ọrun.
Jesu, Oluwa wa,
mp
Busi ‘fẹ wa nihin;
f
Mu wa de ‘nu ogo,
Lati yìn Ọ titi. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites