Anglican Hymnal
Hush! blessed are the dead
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 524: Hush! blessed are the dead
Ibukun ni f’oku
Hymn:
524
Meter:
6.6.6.6
Season:
Isinku
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
p
Ibukun ni f’okú,
T’o simi le jesu;
Awọn t’o gb’ ori wọn
Le okan aiya Rẹ̀.
mf
Iran ‘bukun l’eyi,
Ko si ‘bòju larin;
Nwọn ri Ẹn’ Imọlẹ̀,
Ti nwọn ti fẹ lairi.
Nwọn bọ lọwọ aiye,
Pẹlu aniyàn rẹ̀;
Nwọn bọ lọwọ ewu,
T’o nrin l’ ọsan, l’oru.
mp
Lori iboji wọn,
L’awa nsọkun lonik
Nwọn j’ ẹn’ ire fun wa,
T’ a kì y’o gbagbe lai.
p
A k’yo gbohùn wọn mọ,
Ohùn ifẹ didun;
Lat’ oni lọ, aiye
Kì o tun mọ̀ wọn mọ.
mp
Ẹnyin oninure,
Ẹ fi wa sìlẹ̀ lọ;
Ao sọkun nyin titi,
Jesu pa sọkun ri.
cr
Ṣugbọn a fẹ gbóhùn
Olodumare na;
f
Y’o kọ, y’o si wipe,
ff
Ẹ dide, ẹ si yọ̀. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites