Anglican Hymnal
Now the laborer’s task is o’er;
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 518: Now the laborer’s task is o’er;
Lala alagbase tan
Hymn:
518
Meter:
7.7.7.7.8.8
Season:
Isinku
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Lala alagbṣe tan;
Ọjọ ogun ti pari;
cr
L’ ebute jijìn réré
Ni ọkọ̀ rẹ̀ ti gùn si:
p
Baba, labẹ itọju Rẹ,
L’ awa f’ iranṣẹ Rẹ yi si.
mf
Nibẹ l’a rẹ’ wọn l’ẹkún;
Nibẹ, nwọn m’ ohun gbogbo;
di
Nibẹ l’ Onidaj’ otọ
Nda iṣẹ aiye wọn wò.
p
Baba, labẹ, &c.
mf
Nibẹ l’ oluṣ’ agùtan
Nko awọn agutan lọ;
di
Nibẹ̀ l’ o ndabòbo wọn,
Kòríkò ko le de ‘bẹ̀.
p
Baba, labẹ, &c.
mp
Nibẹ̀ l’ awọn ẹlẹṣẹ,
Ti ntẹju m’ agbelebu,
cr
Y’o mọ̀ ifẹ Kristi tan,
L’ẹsẹ Rẹ̀ ni Paradis,
p
Baba, labẹ, &c.
mf
Nibẹ l’ agbara Eṣu
Kò le b’ ayọ̀ wọn jẹ mọ;
Kristi Jesu sa nṣọ wọn,
On t’o ku fun ‘dane wọn.
p
Baba, labẹ, &c.
pp
“Erupè fun erupe,”
L’ ède wa nisisiyi;
A tẹ silẹ lati sùn
cr
Titi d’ọjọ ajinde.
p
Baba, labẹ, &c. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites