Anglican Hymnal
How sweet the hour of closing day
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 516: How sweet the hour of closing day
Igba asale ti dun to
Hymn:
516
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Isinku
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Igba aṣalẹ ti dùn to !
Ti ara tù ohun gbogbo:
‘Gbat’ ìtanṣan orùn alẹ
Ba ntànmọlẹ s’ ohun gbogbo!
Bẹni ‘kẹhìn onigbagbọ,
On a simi l’ alafia;
cr
Igbagbọ to gbona janjan
A mọlẹ ninu ọkàn rẹ̀.
mf
Imọlẹ kan mọ loju rẹ̀,
Ẹrin sì bọ ni ẹnu rẹ̀;
O nf’ ède t’ ahọn wa kò mọ̀
Sọ̀rọ ogo t’o sunmọle.
cr
Itanṣan ‘mọlẹ t’ ọrun wá,
Lati gba niyanju lọna;
Awọn angẹl duro yika
Lati gbe lọ s’ibugbe wọn.
mp
Oluwa, jẹ k’ a lọ bayi,
K’a ba Ọ yọ̀, k’a r’ oju Rẹ;
cr
Tẹ̀ aworan Rẹ s’ ọkàn wa,
Si kọ́ wa b’ a ti ba Ọ rìn. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites