Anglican Hymnal
Hark! They are now at the shore
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 515: Hark! They are now at the shore
A! nwon ti gun s’ ebute
Hymn:
515
Meter:
7.6.7.7.6
Season:
Isinku
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
A ! nwọn ti gún s’ ebute,
p
Loke ọrun; Loke ọrun;
mf
Ebi kò ni pa wọn mọ,
Nwọn bọ lọwọ irora,
f
Loke ọrun; Loke ọrun;
A ! nwọn kò wa fitilà,
p
Loke ọrun; Loke ọrun;
‘Mọlẹ̀ ni l’ọjọ gbogbo,
Jesu si n’ Imọlẹ wọn,
f
Loke ọrun; Loke ọrun;
A ! wura n’ ita wọn jẹ,
p
Loke ọrun; Loke ọrun;
Ogo ‘bẹ si pọ̀ pupọ,
Agbo Jesu ni nwọn jẹ
f
Loke ọrun; Loke ọrun;
A ! otutu ki mu wọn,
p
Loke ọrun; Loke ọrun;
Oworẹ́ wọn ti kọja,
Gbogbo ọjọ l’o dara;
f
Loke ọrun; Loke ọrun;
A ! nwọn ckun ìja ‘ja,
p
Loke ọrun; Loke ọrun;
Jesu l’ o ti gbà wọn là,
T’ awọn Tirẹ l’ o sì nrìn,
Loke ọrun; Loke ọrun;
A ! nwọn kò ni sọkun mọ,
p
Loke ọrun; Loke ọrun;
Jesu sa wà lọdọ wọn,
Lọdọ Rẹ̀ ni ayọ̀ wà,
f
Loke ọrun; Loke ọrun.
A ! a o dapọ mọ wọn,
p
Loke ọrun; Loke ọrun;
A nreti akoko wa,
f
‘Gba Oluwa ba pè ni
di
S’ oke ọrun; S’ oke ọrun. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites