Anglican Hymnal
Thy way, not mine, O Lord
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 512: Thy way, not mine, O Lord
Ona Re, Oluwa
Hymn:
512
Meter:
6.6.6.6
Season:
Alaisan
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Ọna Rẹ, Oluwa,
B’o ti wù k’o dí to,
Fi ọwọ Rẹ tọ́ mi,
Yàn ipa mi fun mi.
p
B’o rọrùn, b’o ṣoro,
Daradara l’o jẹ;
B’o run tab’ o wọ́ ni,
Dandan s’isimi ni.
Nkò gbọdọ yàn ‘pín mi,
Nko tilẹ jẹ́ yàn a;
Yan fun mi, Ọlọrun,
Bẹni ngo rìn dede.
Ijọba t’emi nwá,
Tirẹ ni; jẹ k’ọna
T’o re ‘bẹ̀ jẹ Tirẹ;
Bi bẹkọ ngo nṣìna.
p
Gbà ago mi, fayọ̀
cr
Tab’ ibanujẹ kun;
B’o ti tọ́ l’oju Rẹ,
Yàn ‘re tab’ ibi mi.
Yàn ọrẹ́ mi fun mi,
p
Aìsan tab’ ilera;
Yàn aniyan fun mi,
Aini tabi ọrọ̀.
Yiyàn k’ iṣe t’emi,
Ninu ohunkohun;
Iwọ ṣ’olutọ mi,
Ọgbọn on gbogbo mi. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites