Anglican Hymnal
Oh, the bitter shame and sorrow
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 509: Oh, the bitter shame and sorrow
O s’ ohun t’o ti mi loju
Hymn:
509
Meter:
8.7.8.8.7
Season:
Alaisan
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
O ṣ’ ohun t’o tì mi loju,
Pe, nigba kan l’aiye mi,
p
Olugbala nkanu lasan,
O npè mi, mo si ndahun pe,
“T’ emi ṣa, nkò náni Rẹ.”
Ṣugbọn O ri mi; mo si wo
L’ or’ igi agbelebu;
Mo si gbọ́, “Fijì wọn Baba,”
Ọkàn mi f’ inira wipe,
“Em’ o nàni Rẹ diẹ.”
p
Lojojumọ li anu Rẹ̀
Nṣe ‘wosàn fun ọkàn mi,
f
Agbara at’ ifẹ l’ O fi
Nfa mi mọra, mo si wipe,
“Ngo náni Rẹ diẹ si.”
f
Ifẹ Rẹ ga jù ọrun lọ,
O si jìn jù okun lọ;
Ifẹ Rẹ na l’ o ṣẹgun mi,
Jẹ ki nlè wi nitotọ pe,
“Em’ o wa fun Ọ titi.” Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites