Anglican Hymnal
The voice that breathed o'er Eden,
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 503: The voice that breathed o'er Eden,
Ire t’ a su ni Eden
Hymn:
503
Meter:
7.6.7.6
Season:
Igbeyawo
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ire t’ a sú ni Eden,
N’ igbeyawo ‘kini,
Ibukun t’ a bukun wọn,
O wà sibẹ̀ sibẹ̀.
Sibẹ titi di oni,
N’ igbeyawo Kristian,
Ọlọrun wà larin wa,
Lati sure fun wa.
Ire ki nwọn lè ma bi,
Ki nwọn k’o sì ma rẹ̀;
Ki nwọn ni dapọ mimọ́,
T’ ẹnikan k’yo le tú.
p
Ba ni pé, Baba, si fà
cr
Obinrin yi f’ ọkọ;
Bi O ti fi Efa fun
Adam lọjọ kini.
p
Ba wa pé Immanucli,
cr
Si so ọwọ wọn pọ̀,
B’ ẹda meji ti papọ̀
L’ ara ìjinlẹ Rẹ.
p
Ba wa pé, Ẹmi Mimọ́,
cr
F’ ibukun Rẹ fun wọn:
Si ṣe wọn ni aṣepé,
Gẹgẹ b’ O ti ma ṣe.
mf
Fi nwọn abẹ abò Rẹ,
K’ ibi kan má ba wọn;
‘Gba nwọn nparà ile Rẹ,
Ma tọju ọkàn wọn.
cr
Pẹlu wọn, l’ ọj’ aiye wọn,
At’ ọkọ at’ aya;
f
Titi nwọn o de ọdọ Rẹ,
N’ ile ayọ̀ l’ ọrun. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites