Anglican Hymnal
Hosanna! raise the pealing hymn
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 493: Hosanna! raise the pealing hymn
Hosanna! e korin soke
Hymn:
493
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Hosanna ! ẹ korin sokè,
S’ ọmọ nla Dafidi;
Pẹlu Kẹrub ati Seraf
K’ a yin Ọm’ Ọlọrun.
mp
Hosanna ! eyi na nikan,
L’ ahọn wa le ma kọ;
cr
Iwọ kì o kẹgàn ewe,
Ti nkọrin ìyin Rẹ.
f
Hosanna ! Alufa, Ọba,
Ẹbun Rẹ ti pọ̀ to !
Ẹjẹ Rẹ l’ o jẹ ìye wa,
Ọrọ Rẹ ni onjẹ.
mf
Hosanna ! Baba, awa mu
Ọrẹ wa wá fun Ọ,
Ki ṣe wura on ojia,
Bikoṣe ọkàn wa.
Hosanna ! Jesu, lẹkan ri,
O yìn awọn ewe;
cr
Ṣanu fun wa, si f’eti si
Orin awa ewe.
mf
Jesu, b’ o ba rà wa paa,
T’ a si wọ̀ jọba Rẹ;
A o fi harpu wura kọ
Hosanna titi lai. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites