Anglican Hymnal
Do no sinful action
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 491: Do no sinful action
Mase huwa ese
Hymn:
491
Meter:
6.5.6.5
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Máṣe huwa ẹ̀ṣẹ,
Má sọ̀rọ ‘binu;
Ọmọ Jesu l’ ẹ ṣe,
Ọmọ Oluwa.
mf
Krist jẹ oninure,
At’ ẹni mimọ́;
Bẹ l’ awọn ọmọ Rè
Yẹ k’o jẹ mimọ́.
p
Ẹmi ibi kan wà,
T’ o nṣọ ìrin rẹ;
O si nfẹ dan ọ wò,
Lati ṣe ibi.
Ẹ má ṣe gbọ́ tirẹ̀.
B’ o tilẹ̀ ṣoro
Lati ba Eṣu jà,
Lati ṣe rere.
mf
Ẹnyin ti ṣe ‘leri
Ni ọmọ-ọwọ,
Lati k’ Eṣu silẹ,
Ati ọ̀na rẹ̀.
Ọm’ ogun Krist ni nyin,
Ẹ kọ́ lati bá
Ẹṣẹ inu nyin jà;
Ẹ ma ṣe rere.
f
Jesu l’Oluwa nyin,
cr
O ṣe ẹnire;
Ki ẹnyin ọmọ Rẹ̀
Si ma ṣe rere. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites