Anglican Hymnal
Ye little ones keep close to God
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 482: Ye little ones keep close to God
Omode, e sunm’ Olorun
Hymn:
482
Meter:
8.8.8.8
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ọmọde, ẹ sunm’ Ọlọrun,
p
Pẹlu irẹlẹ̀ at’ ẹ̀ru;
Ki ekun gbogbo wolẹ̀ fun
Olugbala at’Ọrẹ́ wa.
mf
Oluwa, jẹ k’ anu Rẹ nla,
Mu wa kun fun ọpẹ si Ọ;
Ati b’ a ti nrin lọ l’ aiye,
K’ a ma ri ọpọ anu gbà.
Oluwa! m’erò buburu,
Jinna réré si ọkàn wa;
L’ ojojumọ fun wa l’ọgbọ́n,
Lati yan ọnà toro nì.
p
Igba aisàn, at’ ilera
Igba aini tabi ọrọ̀;
pp
Ati l’akoko ikú wa,
f
Fi agbara Tirẹ gbà wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites