Anglican Hymnal
Jesus Thou who lives in Heaven
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 480: Jesus Thou who lives in Heaven
Jesu t’ o wa l’ oke orun
Hymn:
480
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Jesu t’o wà l’oke ọrun,
p
Sọkalẹ d’enia, o ku;
Ninu Bibeli l’a lè ri,
Bi On iti ma ṣe rere.
O nkiri, o si nṣe rere,
O nla ‘ju awọn afọju;
Ọ̀pọ awọn t’o si yarọ,
O ṣanu wọn, o si wò wọn.
Jù wọnni lọ, o wi fun wọn,
Ohun wọnni t’Ọlọrun fẹ;
O si ṣe ẹnit’ o tutù,
Yio si gbọ́ t’ awọn ewe.
p
Ṣugbọn ikú t’o kú buru,
A fi kọ́ ‘ri agbelebu;
Ọwọ rere t’o ṣe nkan yi,
p
Nwọn kan mọ ‘gi agbelebu.
O mọ̀ b’ enia ti buru,
O mọ b’ iyà ẹ̀ṣẹ ti ri;
Ninu anu Jesu wipe,
On o gbà iyà ẹ̀ṣẹ jẹ.
p
Bẹ l’ o kú nitori yi nà,
cr
O d’ enia, k’o ba le ku;
Bibeli ní, o t’ ọrun wá,
K’o lè dari ẹ̀ṣẹ ji ni.
Ọlọrun o si f’ẹṣẹ jì
Awọn t’o ronupiwada;
Jẹ k’a ji kùtu w’oju Rẹ̀,
K’a si gbà ẹ̀kún ore Rẹ̀. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites