Anglican Hymnal
Hark! the glad sound! the Saviour comes
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 48: Hark! the glad sound! the Saviour comes
Gbo ’gbe ayo ! Oluwa de
Hymn:
48
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Bibo Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Gbọ ‘gb ayọ! Oluwa de,
Jesu t’a ṣèleri;
Ki gbogbo ọkàn mura de,
K’ ohùn mura kọrin.
O de lati t’ondè silẹ
L’ oko ẹru Eṣu;
ff
‘Lẹkùn ‘de fọ niwaju Rè.
Ṣẹkẹṣẹkẹ ‘rin dá.
mf
O de larin ‘bajẹ aiye
Lati tàn ‘mọlẹ Rè,
Lati mu k’awọn afọju
Le f’oju wọn riran.
p
O de, ‘tunu f’ọkàn ‘rora,
Iwòsan f’agbọgbe;
cr
Pẹlu ‘ṣura or’ọfẹ Rè
Fun awọn talaka.
un
Hosanna, Ọba ‘lafia,
Ao kede bibọ Rẹ:
Gbogbo ọrun y’o ma kọrin
Orukọ t’a fẹràn. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites