Anglican Hymnal
Around the throne of God in heaven
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 479: Around the throne of God in heaven
Yika or’ ite Olorun
Hymn:
479
Meter:
8.6.8.6.8
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Yikà or’ itẹ Ọlọrun,
Ẹgbẹrun ewe wà;
Ewe t’ a dari ẹ̀ṣẹ ji,
Awọn ẹgbẹ mimọ́:
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
Wo ! olukuluku wọn wọ̀
Aṣọ àla mimọ;
Ninu imọlẹ ailopin,
At’ ayọ̀ ti ki ṣá,
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
mf
Kil’ o mu wọn de aiye na,
Ọrun t’o ṣe mimọ́,
cr
Nib’ alafia at’ ayọ̀,
Bi nwọn ti ṣe de ‘bẹ̀?
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
p
Nitori Jesu ta ‘jẹ Rẹ̀,
Lati k’ẹṣẹ wọn lọ;
A rì wọn ninu ẹjẹ na,
Nwọn di mimọ́ laulau;
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
mf
L’ aiye, nwọn wá Olugbala,
Nwọn fẹ orukọ Rẹ̀’
cr
Nisisiyi nwọn r’ oju Rẹ̀,
Nwọn wà niwaju Rẹ̀;
Nkọrin Ogo, ogo, ogo.
p
Orisun na ha nṣàn loni?
Jesu, mu wa de ‘bẹ̀;
K’a le ri awọn mimọ́ na,
cr
K’ a si ba wọn yìn Ọ,
f
Nkọrin Ogo, ogo, ogo. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites