Anglican Hymnal
There is a path that leads to God
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 478: There is a path that leads to God
Ona kan l’o ntoka sorun
Hymn:
478
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ọna kan l’o ntọka sọrun,
Iṣina ni ‘yoku;
Hiha si l’oju ọ̀na na,
Awọn Kristian l’o fẹ.
Lat’ aiye, o lọ tàrata,
O sì la ewu lọ;
cr
Awọn ti nf’ igboyà rìn i,
Y’o d’ọrun nikẹhìn.
mf
Awọn ewe y’o ha ti ṣe
Le là ewu yi ja?
‘Tori idẹ̀kùn pọ̀ lọnà
F’ awọn ọdọmọde !
p
Gbigboro lọna t’ọ̀pọ nrìn,
O sì tẹju pẹlu !
Mo sì mọ pe lati dẹṣẹ
Ni nwọn ṣe nrìn nibẹ.
mf
Ṣugbọn k’ẹsẹ mi ma bà yẹ̀,
Ki nmá sì ṣako lọ,
Oluwa, jọ ṣ’olutọ mi,
Emi ki o ṣina.
Njẹ mo le lọ l’ ais’ ifoya,
Ki ngbẹkẹl’ ọrọ Rẹ̀;
p
Apa Rẹ̀ y’o ṣ’ agutan Rẹ̀,
Y’o sì ko wọn de ‘le.
cr
Bẹni ngo là ewu yi ja
Nipa itọju Rẹ̀;
f
Ngo tẹjumọ ‘bode ọrun
Titi ngo fi wọle. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites