Anglican Hymnal
Heavenly Father, send your light
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 474: Heavenly Father, send your light
Olorun, ran imole Re
Hymn:
474
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Ọlọrun, ran imọlẹ Rẹ,
Si awa ọmọ Rẹ;
K’ awa lè sìn k’ a si fẹ Ọ
Lat’ ewe tit’ opin.
p
Awa dẹṣẹ, a si fọju,
A nrìn l’ ọnà ‘parun;
L’ ọkàn, ati n’ ìwa l’ a fi
Jẹ́ ọta Ọlọrun.
Ṣugbọn ọrẹ́ at’ olutọ,
Nwọn nkó wa n’ ijanu;
Nwọn nkọ́ wa, k’ a wá oju Rẹ,
T’ a kò lè wá l’ asan.
A gb’ oju wa s’ ori okè,
Nib ‘gbala ti nwá;
f
‘Wọ Orùn Ododo, dide,
Lati m’ ara wa yá.
f
Dide, ràn s’ aiye oṣi yi,
Ma ràn titi aiye !
Titi awa o fi dàgba,
Ma f’ọnà Kristian hàn. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites