Anglican Hymnal
Once in royal David's city
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 467: Once in royal David's city
Nigba kan ni Betlehemu
Hymn:
467
Meter:
8.7.8.7.7.7
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Nigba kan ni Bẹtlẹhẹmu,
Ile kekere kan wà;
Nib’ iya kan tẹ ‘mọ rẹ̀ si,
Lori ibujẹ ẹran;
Maria n’iya Ọmọ na,
Jesu Krist si l’Ọmọ na.
O t’ ọrun wá sode aiye,
On l’ Ọlọrun Oluwa;
O f’ile ẹran ṣe ile,
‘Bujẹ ẹran fun ‘bùsun.
Lọdọ awọn òtoṣi
Ni Jesu gbe li aiye.
Ni gbogbo igba ewe Rẹ̀,
O ngbọràn, o sì mb’ ọla,
O nfẹràn o sì ntẹriba,
Fun iya ti ntọju Rẹ̀:
O yẹ ki gbogb’ ọmọde
K’ o ṣe olugbọran bẹ.
‘Tori On jẹ awòṣe wa,
A ma dagba bi awa,
O kere, kò le da nkan ṣe,
p
A ma sọkun bi awa;
O sì le ba wa darò,
f
O le ba wa yọ pẹlu.
Ao fi’oju wa ri nikẹhìn
Ni agbara ifẹ Rẹ̀,
Nitori Ọmọ rere yi
Ni Oluwa wa lọrun;
O ntọ́ awa ọmọ Rẹ̀
S’ ọna ibiti On lọ.
Ki ṣe ni ibujẹ ẹran,
Nibiti malu njẹun,
L’ awa o ri; ṣugbọn lọrun,
Lọwọ ọtun Ọlọrun,
‘Gbà ‘wọn ‘mọ Rẹ̀ b’ iràwọ
Ba wà n’nu aṣọ àla. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites