Anglican Hymnal
Jesus loves me! This I know,
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 465: Jesus loves me! This I know,
Jesu fe mi, mo mo be
Hymn:
465
Meter:
7.7.7.7
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Jesu fẹ mi, mo mọ̀ bẹ,
Bibeli l’o sọ fun mi;
Tirẹ l’awọn ọmọde,
p.f Nwọn kò lagbara, On ni.
p
Jesu fẹ mi, Ẹn’ t’o kú
Lati ṣi ọrun silẹ;
mf
Yio wẹ̀ ẹ̀ṣẹ mi nù:
Jẹki ọmọ Rẹ̀ wọle.
p
Jesu fẹ mi sibẹ si,
Bi emi tilẹe ṣ’aìsàn
cr
Lor’ akete aisan mi,
Yio t’itẹ Rẹ̀ wá ṣọ́ mi.
mf
Jesu fẹ mi, y’o duro
Ti mi ni gbogb’ ọna mi,
Gba mba f’aiye yi silẹ̀,
Y’o mu mi re ‘le ọrun. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites