Anglican Hymnal
Little drops of water
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 461: Little drops of water
Opo ikan omi
Hymn:
461
Meter:
6.5.6.5
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ọpọ íkán omi,
Yanrin kekeke;
cr
Wọnyi l’o f’okun nla,
At’ ilẹ̀ẹaiye.
mp
Iṣẹju wa kọkan,
Ti a kò kàsi,
cr
L’ o nd’ ọdun aimoye
Ti ainipẹkun.
mp
Iwa ore diẹ,
Ọrọ̀ ‘fẹ diẹ,
cr
L’ o ns’ aiye di Eden,
Bi oke ọrun.
p
Iṣìṣe kekeke
L´o nmọkàn ṣìna,
Kuro l` ọ̀na rere,
Si ipa ẹ̀ṣẹ.
mf
Iṣẹ anu diẹ
T’a ṣe l’ọmọde,
cr
Di ‘bukun f’orilẹ
T’o jina réré.
f
Awọn ewe l’ogo
Ngberin Angẹli;
di
Ṣe wa yẹ Oluwa
p
F’ẹgbẹ mimọ́ wọn. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites