Anglican Hymnal

Thou God of love, Spring of Mercy

Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.

Hymn 46: Thou God of love, Spring of Mercy

Olorun ’fe, Isun anu

Hymn: 46
Meter: C.M (8.6.8.6)
Season: Ikore
Add Favourite
  1. f Olorun ‘fe Isun anu,
    Ore Rẹ ti pọ̀ to!
    Oriṣi akoko t’o ndé
    L’o nkédé ajò Rẹ.

  2. Nigbat’ àgbẹ gbìn ọ̀gbin rè,
    T’o rì mọ ‘nu ilẹ,
    Iwọ m’ akoko ti o nhù,
    O sì rán òjo wà.

  3. f Tirẹ l’ agbara t’ojo ni,
    T’o nmu ‘rugbin dàgba;
    ‘Wọ l’o nrán ‘mọlẹ orun wá,
    p Ati ìri pẹlu.

  4. Akoko ‘rugbìn on ‘kore,
    Iwọ l’o fi fun wa;
    mf Má jẹ k’a gbagbe lati mọ́
    Ibi ‘bùkún ti nwá.

  5. Isun ifẹ, ‘Wọ n’ iyìn wa;
    Iwọ l’a nkọrin si,
    Gbogbo ẹda l’ o sì dalu
    N’nu iyìn didùn na. Amin.