Anglican Hymnal
Now the day is over
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 459: Now the day is over
Ojo oni lo tan
Hymn:
459
Meter:
6.5.6.5
Season:
Orin Omode
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Ọjọ oni lọ tan,
Oru sunmọle:
Okunkun ti de na,
Ilẹ si ti ṣú.
Okunkun bo ilẹ̀,
Awọn ‘rawọ yọ;
Ẹranko at’ẹiye,
Lọ si bùsun wọn.
mf
Jesu f’orun didùn
F’ ẹni alarẹ̀;
p
Jẹ ki ibukun Rẹ
Pa oju mi de.
Jẹ k’ ọmọ kekere
La alá rere;
Ṣ’ ọlọkọ̀ t’ewu nwu
Ni oju omi.
p
Ma tọju alaisan
Ti kò r’orun sùn;
mf
Awọn ti nro ibi,
Jọ da wọn l’ẹkun.
p
Ninu gbogbo oru,
Jẹ k’ angẹli Rẹ
Ma ṣe oluṣọ mi,
L’ori ẹni mi.
cr
Gbat’ ilẹ̀ ba si mọ́,
Jẹ k’ emi dide;
f
B’ ọmọ ti kò l’ ẹ̀ṣẹ
Ni iwaju Rẹ.
ff
Ogo ni fun Baba,
Ati fun Ọmọ,
Ati f’ Ẹmi Mimọ́,
Lai ati lailai. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites