Anglican Hymnal
Stand, soldier of the cross
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 447: Stand, soldier of the cross
Duro, omo ogun
Hymn:
447
Meter:
S.M (6.6.8.6)
Season:
Baptismu Agba
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Duro, ọmọ ogun,
F’ ẹnu rẹ sọ f’aiye;
Si jẹjẹ pe òfo l’aiye,
Nitori Jesu rẹ.
f
Dide, k’a baptis’ rẹ,
K’ o wẹ ẹ̀ṣẹ rẹ nù,
Wá b’ Ọlọrun dá majẹmu,
Sọ ‘gbagbọ rẹ loni.
Tirẹ ni Oluwa,
At’ ijọba ọrun;
Sa gb’ àmi yi siwaju rẹ,
Ami Oluwa rẹ.
‘Wọ k’ iṣe t’ ara rẹ,
Bikoṣe ti Kristi;
A kọ orukọ rẹ pọ̀ mo
Awọn mimọ́ gbani.
Ni hamọra Jesu,
Kọjuja si Eṣu;
B’o ti wù k’ ogun na le to,
Iwọ ni o ṣẹgun.
Ade didara ni,
Orin na, didun ni,
‘gba t’a ba ko ikogun jọ
S’ ẹsẹ̀ Olugbala. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites