Anglican Hymnal
I THIRST, thou wounded Lamb of God
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 435: I THIRST, thou wounded Lamb of God
Odo Agutan Olorun
Hymn:
435
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Idapo Mimo
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọdọ Agutan Ọlọrun,
Jọ wẹ̀ mi ninu ẹjẹ Rẹ;
Sa jẹ ki nmọ ‘fẹ Rẹ, ‘gbana
Irora dùn, iku l’erè.
f
Fa ọkàn mi kuro l’aiye,
K’ o jẹ k’o ṣe Tirẹ titi;
Fì edidi Rẹ s’ aiya mi,
Edid’ ifẹ titi aiye.
A ! awọn wọnni ti yọ̀ to,
T’ o f’ìha Rẹ ṣe ‘sadi wọn!
Nwọn fi Ọ ṣe agbara wọn,
Nwọn njẹ, nwọn si nmu ninu Rẹ.
mf
O kùn wa loju p’Ọlọrun,
Fẹ m’ awa yi lọ sin’ ogo!
Pe, O sọ ẹrù d’ ọm’Ọba,
Lati ma jẹ fajì lailai!
Baba, mu wa ronu jinlẹ̀,
K’ a lè mọ̀ iṣẹ nlanla Rẹ;
Má ṣai tu okùn ahọn wa,
K’ a lè sọ ibu ifẹ Rẹ.
f
Jesu, Iwọ l’olori wa,
‘Wọ l’a o tẹri wa ba fun,
‘Wọ l’ a o fi ọkàn wa fun,
B’a kù, b’a wà, k’a jẹ Tirẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites