Anglican Hymnal
According to Thy gracious word
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 432: According to Thy gracious word
Gege bi oro ore Re
Hymn:
432
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Idapo Mimo
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Gẹgẹ bi ọ̀rọ ore Rẹ,
Ninu irẹlẹ̀ nla,
Emi o ṣe yi Oluwa,
p
Emi o ranti Rẹ.
mf
Ara Rẹ ti a bù fun mi,
Yio jẹ onjẹ mi;
Mo gbà ago majẹmu Rẹ,
p
Lati ṣe ranti Rẹ.
n
p
Mo lè gbagbe Getsemane,
Ti mo r’ ijamú Rẹ,
pp
Iyà on ogùn ẹjẹ Rẹ,
cr
Ki nma si ranti Rẹ?
mp
Ngo ranti gbogbo ‘rora Rẹ,
At’ ifẹ Rẹ si mi;
cr
Bi o kù ẹmi kan fun mi,
Emi o ranti Rẹ.
pp
‘Gbati ẹnu mi ba pamọ,
Ti iyè mi ba ra,
cr
Ti O ba de n; ijọba Rẹ.
Jesu, jọ ranti mi. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites