Anglican Hymnal
Praise to God, immortal praise,
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 43: Praise to God, immortal praise,
Yin Olorun, yin lailai
Hymn:
43
Meter:
7.7.7.7
Season:
Ikore
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Yìn Ọlọrun, yin lailai
Fun ifẹ ojojumọ;
Orisun ayọ̀ gbogbo,
K’ìyìn Rẹ̀ gb’ẹnu wa kan.
mf
Fun irè t’oko nmú wà;
Fun onjẹ t’a nmù l’ọgba;
Fun eso igì pẹlu;
At’ororo ti a nlò,
Fun gbogb’ ẹran ọ̀sin wa
T’on ṣiri ọkà gbigbó;
Ọrun ti nsẹ̀ ‘rì silẹ;
Orùn ti nm’ oru rẹ̀ wá.
Gbogbo nkan t’ẹrun nmu wá
Kakiri gbogbo ilẹ;
At’ eso ìgba òjo
Lat’ inu ẹ̀kún rẹ̀ wá.
f
‘Wọ l’ẹlẹbùn gbogbo wọn
Orisun ibukun wa;
‘Torina ọkàn wa y’o
F’ iyin at’ ọpẹ fun Ọ.
mp
Ijì lile iba jà
K’o ba gbogbo ọkà jẹ;
K’eso igi wọ́ dànu
Ki akoko rẹ̀ to pe;
Ajara ‘ba má so mọ́,
Ki igi gbogbo sì gbẹ,
K’ẹran ọ̀sin gbogbo kú
K’ẹran igbẹ tán pẹlu;
mf
Sibẹ, Iwọ l’ọkàn wa
Y’o f’iyìn at’ọpẹ fun;
Gbat’ ibukun gbogbo tan
cr
Ao sa fẹ Ọ fun ‘ra Rẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites