Anglican Hymnal
O Fount of good, for all your love
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 429: O Fount of good, for all your love
Wo orison ohun rere
Hymn:
429
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Itore Anu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
‘Wọ orisun ohun rere,
Awa fẹ ṣe ‘fẹ rẹ;
Ohun wo l’a lè fi fun Ọ,
Ọba gbogbo aiye?
p
L’aiye yi, ‘Wọ ní otoṣi,
T’o jẹ enia Rẹ:
Orukọ wọn n’Iwọ njẹwọ
Niwaju Baba Rẹ.
p
‘Gba nwọn ba nke n’ inira wọn,
Ohun Rẹ l’ awa ngbọ́;
‘Gba ba si nṣe itọju wọn,
Awa nṣe ‘tọju Rẹ.
f
Jesu, má ṣai gbà ọrẹ wa,
Si f’ ibukun Rẹ si;
Ma f’ ibukun Rẹ s’ ẹbùn wa,
Fun awọn t’a nfi fun.
Fun Baba, Ọmọ at’ Ẹmi,
Ọlọrun ti a nsìn;
f
Ni ki a ma fi ogo fun,
Titi aiyeraiye. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites