Anglican Hymnal
Come, let us join our cheerful songs
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 425: Come, let us join our cheerful songs
E wa k’ a da orin wa po
Hymn:
425
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ijo Mimo l'aiye
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ẹ wá k’ a da orin wa pọ̀
Mọ t’awọn Angẹli;
Ẹgbẹgbẹrun ni ohùn wọn,
Ọkan ni ayọ̀ wọn.
Nwọn nkọrin pe, “Ọla nla ye
Ọdagutan t’a pa:”
K’ a gberin pe, “Ọla nla yẹ:’
p
‘Tori O kú fun wa.
mf
Jesu, li O yẹ lati gba,
Ọla at’ agbara:
cr
K’ ìyin t’ẹnu wa kò lè gbà,
Jẹ Tirẹ, Oluwa.
f
K’awọn t’o wà loke ọrun,
At’ ilẹ, at’ okun;
Dapọ lati gb’ogo Rẹ ga,
Jumọ yin ọla Rẹ.
ff
Ki gbogbo ẹda d’ohùn pọ̀,
Lati yìn orukọ
Ẹnit’ o joko lor’itẹ́,
Ki nwọn si wolẹ̀ fun. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites