Anglican Hymnal
Blessed are they in Jesus
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 422: Blessed are they in Jesus
Alabukun n’nu Jesu
Hymn:
422
Meter:
7.7.7.7.7.7
Season:
Ijo Mimo l'aiye
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Alabukun n’nu Jesu
Ni awọn ọm’Ọlọrun,
Ti a fi ẹjẹ Rẹ̀ rà
f
Lat’ inu iku s’iyè;
cr
A ba jẹ kà wa mọ wọn,
L’aiye yi, ati l’ọrun.
f
Awọn ti a da l’are
Nipa ore-ọfẹ Rè;
A wẹ̀ gbogbo ẹṣẹ wọn,
Nwọn o bọ́ l’ọjọ ‘dajọ;
cr
A ba jẹ kà wa, &c.
f
Nwọn ns’eso ore-ọfẹ;
Ninu iṣẹ ododo,
Irira l’ẹṣẹ si wọn,
Ọr’Ọlọrun ngb ‘nu wọn;
cr
A ba jẹ kà wa, &c.
mp
Nipa ẹj’Ọdagutan,
Nwọn mba Ọlọrun kẹgbẹ,
Pẹlu Ọla-nla Jesu,
A wọ̀ wọn l’aṣọ ogo;
cr
A ba jẹ kà wa, &c. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites