Anglican Hymnal
King of Saints, to whom the number
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 419: King of Saints, to whom the number
Oba awon eni mimo
Hymn:
419
Meter:
8.7.8.7
Season:
Ijo Olorun ni oke Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ọba awọn ẹni mimọ
T’o mọ̀ ‘ye awọn ‘rawọ;
Ọpọ enit’ ẹda gbagbe
Wà yika itẹ Rẹ lai;
mf
‘Mọlẹ ti kuku aiye bò,
Ntàn ‘mọlẹ roro loke,
Nwọn jẹ ọm’-alade lọrun,
Ẹda gbagbe wọn laiye.
mf
Lala at’ ìya wọn fun Ọ,
Ẹda kò rohin rẹ̀ mọ;
Iwa rere wọn farasin,
Oluwa nikan l’o mọ.
p
Nwọn farasin fun wa, ṣugbọn
A kọ wọn s’iwe iye:
Igbagbọ, adurà, suru,
Lala on ‘jakadi wọn.
mf
Nwọn mọ̀ iṣura Rẹ lọhun;
Kà wa mọ́ wọn, Oluwa,
Nigbat’ O ba nṣiro ọṣọ,
Ti mbẹ lara ade Rẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites