Anglican Hymnal
Come, let us join our friends above
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 417: Come, let us join our friends above
Wa k’a da m’ awon ore wa
Hymn:
417
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ijo Olorun ni oke Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Wá k’a dà m’awọn ọ̀rẹ́ wa,
Ti nwọn ti jère na;
N’ ifẹ k’a f’ọkàn ba wọn lọ
Sode ọrun lọhun.
K’awọn t’aiye d’orin wọn mọ́,
T’ awọn t’o lọ s’ogo;
Awa l’aiye, awọn l’ọrun,
Ọkan ni gbogbo wa.
mp
Idile kan n’nu Krist ni wa.
Ajọ kan l’a si jẹ;
di
Iṣàn omi kan l’o yà wa.
p
Iṣàn omi iku.
f
Ẹgbẹ ogun kan t’Ọlọrun,
Aṣẹ Rẹ̀ l’a si nṣe;
mp
Apakan ti wọ́dò na ja,
p
Apakan nwọ lọwọ!
cr
Ẹmi wa fẹrẹ dàpọ na,
Y’o gb’Ade bi ti wọn;
f
Ao yọ̀ s’àmi Balogun wa,
Lati gbọ́ ipè Rẹ̀.
cr
Jesu, ṣọ wa, ṣ’amọna wa,
Gbat’ onikọ̀ ba de;
f
Oluwa, pín omi meji,
Mu wa gunlẹ l’ayọ̀. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites