Anglican Hymnal
Prepare O Sinner To Be Wise
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 412: Prepare O Sinner To Be Wise
Mura, elese, lati gbon
Hymn:
412
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ikilo ati Ipe
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Mura, ẹlẹṣẹ, lati gbọ́n,
Má duro de ọjọ ọla;
Niwọ̀n b’o ti kẹgan ọgbọ́n,
Bẹ l’o si ṣoro lati ri.
mf
Mura lati bere anu,
Má duro de ọjọ ọla;
Ki igbà rẹ ko má bà tán,
p
Ki ọjọ alẹ yi to tán.
f
Mura, ẹlẹṣẹ, k’o padà,
Má duro de ọjọ ọla;
p
Nitori k’egun má ba ọ,
K’ ọjọ ọla t’o to bẹrẹ̀.
f
Mura lati gbà Ibukun,
Má duro de ọjọ ọla;
p
Ki fitila rẹ má ba ku,
K’iṣẹ rere rẹ to bẹrẹ.
f
Oluwa, y’ẹlẹṣẹ padà,
Ji kuro ninu were rẹ̀;
Má jẹ k’o tàpa s’imọ̀ Rẹ,
p
K’o ma f’egbe rẹ se ‘lọra. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites