Anglican Hymnal
You children of the dead
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 410: You children of the dead
Enyin omo oku
Hymn:
410
Meter:
6.6.6.6.8.8
Season:
Ikilo ati Ipe
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ẹnyin ọmọ okú,
cr
T’ o wà ninu ẹ̀ṣẹ;
Gbohun ihinrere,
Jesu ranṣẹ si nyin.
p
Ẹnyin ẹni-egbe, b wá;
Ni apa Jesu àye mbẹ.
Ẹ má pẹ titi mọ,
Má wá awawi mọ́;
O ni k’ ẹ wá loni,
Bo ẹ tilẹ̀ ‘toṣi;
Gbogbo nka ṣetan, ẹlẹṣẹ:
Fun gbogbo ọkàn, àye mbẹ.
f
Gbà ọ̀rọ t’ọrun gbọ́,
Ti oniṣẹ Rẹ̀ nsọ;
Alanu l’Oluwa,
Otọ l’orukọ Rẹ̀;
Ọkan iṣubu, pada wá,
S’ aigbẹkẹle nù, àye mbẹ.
f
Ẹnyin t’ ifẹ rẹ̀ fà,
Ẹ sunmọ ọdọ Rẹ̀,
Kristi t’oke pè nyin,
Ẹ gb’ohùn didùn Rẹ̀;
Ẹnikẹni t’o fẹ k’ o wá,
Ni aiya anu àye mbẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites