Anglican Hymnal
Come, labor on.
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 393: Come, labor on.
Wa, ma sise
Hymn:
393
Meter:
4.10.10.10.4
Season:
Ise Isin
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
Wá, ma ṣiṣẹ.
f
Tani gbọdọ s’ọlẹ ninu oko,
‘Gbati gbogbo enia nkorè jọ?
Kaluku ni Baba paṣẹ fun pe,
“Ṣiṣẹ loni.”
Wá, ma ṣiṣẹ.
Gbà ‘pe’ giga ti angẹli ko ni---
Mu ‘hinrere tọ t’àgbà t’ewe lọ:
di
“Ra ‘gbà pada;” wàwà l’akoko nlọ,
p
Ilẹ ṣú tan.
mf
Wá, ma ṣiṣẹ.
Oko pọ, alagbaṣe kò si to,
cr
A n’ibi titun gbà, a ni ‘pò ‘rọ́;
Ohùn ọ̀nà jijin, at’itosi,
Nkigbe pe, “Wa.”
f
Wá, ma ṣiṣẹ.
Le ‘yemeji on aigbagbọ jinna,
Kò s’alailera ti kò le ṣe nkan:
di
Ailera l’Ọlọrun ama lò jù
Fun ‘ṣẹ́ nla Rẹ̀.
cr
Wá, ma ṣiṣẹ.
‘Simi kò si, nigbat’ iṣe ọsan,
Titi orùn yio fi wọ̀ l’alẹ,
f
Ti awa o si gbọ ohùn ni pe,
“O ṣeun, ọmọ.”
Wá, ma ṣiṣẹ.
Lala na dùn, èrè rẹ̀ si daju.
cr
‘Bukun f’awọn t’o f’ori ti d’opin;
Ayọ̀ wọn, ‘simi wọn, y’o ti pọ̀ to.
p
Lọd’ Oluwa! Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites