Anglican Hymnal
O Spirit of the living God
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 39: O Spirit of the living God
Emi Olorun alaye
Hymn:
39
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Fun Oniruru Igba
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ẹmi Ọlọrun alaye,
N’nu ẹkún ore-ọfẹ Rẹ,
Nibit’ ẹsẹ enia ti tẹ,
Sọkalẹ sori iran wa.
F’ẹbun ahọn, ọkan ife,
Fun wa lati sọrọ ‘fẹ Re,
Bà l’awọn t’o ngbọ́ ọ̀rọ na.
K’okùn kàsẹ̀ ni bibọ̀ Rẹ:
Ki dàrudàpọ di titọ́;
F’ ilera f’ọkàn ailera;
Jẹ ki anu bori ‘binu.
mp
Ẹmi Ọlọrun, jọ pèsè
Gbogbo aiye fun Oluwa:
cr
Mí si wọn b’ afẹfẹ orọ̀,
K’ ọkàn okuta le sọji.
f
Baptis’ gbogb’ orilẹ-ede;
Rohin ‘ṣẹgun Jesu yika;
Yin orukọ Jesu logo
Tit’ araiye yio jẹwọ Rẹ̀. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites