Anglican Hymnal
Through the night of doubt and sorrow
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 381: Through the night of doubt and sorrow
Ninu oru ibanuje
Hymn:
381
Meter:
8.7.8.7
Season:
Ijagun ati Irin Ajo wa
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ninu oru ibanujẹ
L’ awọn ẹgbẹ erò nrin;
Nwọn nkọrin ‘reti at’ ayọ̀,
Nwọn nlọ silẹ ileri.
mf
Niwaju wa nin’ okunkun,
Ni imọlẹ didan ntàn;
Awọn arakọnrin nṣátẹ́,
Nwọn nrin lọ li aifoyà.
cr
Ọkan ni imọlẹ ọrun,
Ti ntàn s’ara enia Rẹ̀;
Ti nle gbogbo ẹ̀ru jina,
Ti ntan yi ọ̀na wa ka.
f
Ọkan ni ìro àjo wa,
Ọkan ni igbagbọ wa;
cr
Ọkan l’ẹni t’ a gbẹkẹle,
Ọkan ni ireti wa.
ff
Ọkan l’orin t’ ẹgbẹrun nkọ,
Bi lati ọkàn kan wa;
di
Ọkan n’ijà, ọkan l’ewu,
cr
Ọkan ni irìn ọrun.
f
Ọkan ni inu didùn wa,
L’ ebute ainipẹkun;
Nibiti Baba wa ọrun,
Y’o ma jọba titi lai.
mf
Njẹ k’ a ma nṣo, arakọnrin,
T’ awa ti agbelebu:
Ẹ jẹ k’ a rù, k’ a si jiya,
Tit’ a o fi ri ‘simi.
f
Ajinde nla fẹrẹ de na,
Boji fẹrẹ ṣi silẹ̀;
ff
Gbogbo okun y’o si tuka,
Gbogbo lala y’o si tán. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites