Anglican Hymnal
The Son of God goes forth to war
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 379: The Son of God goes forth to war
Omo Olorun nlo s’ ogun
Hymn:
379
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ijagun ati Irin Ajo wa
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọmọ Ọlọrun nlọ s’ogun,
Lati gb’ade Ọba:
Ọpagun Rẹ̀ si nfẹ lẹlẹ,
Tal’ o ṣ’ ọmogun Rẹ̀?
mp
Ẹnit o lè mu ago na,
T’ o lè bori ‘rora,
cr
T’o le gbe agbelebu Rẹ̀,
f
On ni Ọmogun Rẹ̀.
mf
Martir ikini t’ o kọ kú,
T’o r’ọrun ṣi silẹ̀;
T’o ri Oluwa rẹ̀ loke,
T’ o pe, k’o gbà on là;
di
T’ on ti ‘dariji l’ẹnu,
Ninu ‘rora ikú,
cr
O bẹbẹ f’ awọn t’o npa lọ:
f
Tani le ṣe bi rẹ?
ff
Ẹgbẹ mimọ; awon wọnni
T’Ẹmi Mimọ bà le;
Awọn akọni mejila,
Ti kò kà iku si:
f
Nwọn f’aiya ràn ida ọta,
Nwọn bá ẹranko jà;
di
Nwọn f’ọrùn wọn lelẹ̀ fun ku,
Tani le ṣe bi wọn?
ff
Ẹgbẹ ogun, t’ agbà, t’ ewe,
T’ọkunrin t’obinrin;
Nwọn y’itẹ́ Olugbala ká,
Nwọn wọ aṣọ funfun.
f
Nwọn de oke ọrun giga,
di
N’nu ‘ṣẹ́ at’ ipọnju:
p
Ọlọrun fun wa l’ agbara
K’ a lè ṣe bi wọn. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites