Anglican Hymnal

Soldiers of Christ, arise,

Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.

Hymn 378: Soldiers of Christ, arise,

Omogun Krist, dide

Hymn: 378
Meter: S.M (6.6.8.6)
Season: Ijagun ati Irin Ajo wa
Add Favourite
  1. f Ọmogun Krist, dide,
    Mu hamọra nyin wọ̀:
    Mu ‘pa t’Ọlọrun fi fun nyin,
    Nipa ti Ọmọ Rẹ̀.

  2. cr Gbe ‘pa Ọlọrun wọ̀,
    T’ Oluwa ọmogun;
    mp Ẹnit’ o gbẹkẹle Jesu,
    O ju aṣẹgun lọ.

  3. mf Ninu ipa rẹ́ nla,
    On ni ki ẹ duro;
    ‘Tori k’ ẹ ba lè jijà na,
    Ẹ di hamọra nyin.

  4. cr Lọ lat’ ipa de ‘pa,
    Ma jà, ma gbadura;
    Tẹ agbara okunkun ba,
    Ẹ jà, k’ ẹ si sẹgun.

  5. Lẹhin ohun gbogbo,
    Lẹhin gbogbo ija,
    K’ ẹ le ṣẹgun n’ipá Kristi,
    K’ ẹ si duro ṣinṣin. Amin.