Anglican Hymnal
O Holy Saviour, Friend unseen
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 371: O Holy Saviour, Friend unseen
Jesu mimo, Ore airi
Hymn:
371
Meter:
8.8.8.6
Season:
Ijagun ati Irin Ajo wa
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Jesu mimọ, Ọrẹ airi,
Olurànlọwọ alaini,
N’nu ayida aiye, kọ́ mi,
K’emi le rọmọ́ Ọ.
Ki nsa n’ idapọ̀ mimọ yi,
Gba ohun t’O fẹ ngo kùn bi?
B’ọkàn mi, b’ẹka ajara,
Ba sa le rọmọ́ Ọ.
Arẹ ti m’ọkàn mi pipọ,
Ṣugbọn o wa r’ibi ‘simi;
Ibukun si de s’ọkàn mi,
T’ori t’o rọmọ́ Ọ.
mf
B’aiye d’ofo mọ mi l’oju,
B’a gbà ọrẹ at’ ará lọ,
di
Ni suru ati laibọ́hùn
L’emo o rọmọ́ Ọ.
mp
Gbat’ o k’emi nikanṣoṣo
L’arin idamu aiye yí,
p
Mo gb’Ohùn ifẹ jẹjẹ na
Wipe, “Sa rọmọ́ Mi.”
cr
B’arẹ ba fẹ mu igbagbọ,
T’ ireti ba si fẹ ṣaki,
f
Kò si ewu fun ọkàn na
Ti o ba rọmọ́ Ọ.
mf
Kò bẹru irumi aiye,
Nitori ‘Wọ wà nitosi;
Kì o si gbọ̀n b’iku ba de,
Tori o rọmọ́ Ọ.
Ire ṣá ni l’ohun gbogbo,
Wọ agbara at’ asa mi;
Olugbala, ki y’o si nkan
Bi mba ti rọmọ́ Ọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites