Anglican Hymnal
Sweet is the work, my God, my King
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 37: Sweet is the work, my God, my King
Didun n’ise na, Oba mi
Hymn:
37
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ojo Oluwa
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Didun n’ iṣẹ ná, Ọba mi,
Lati mà yin orukọ Rẹ,
Lati ṣe ‘fẹ Rẹ l’owurọ,
Lati sọ ọrọ Rẹ l’alẹ.
p
Didùn l’ ọjọ ‘simi mimọ,
Lala kò si fun mi loni:
Ọkàn mi, mà kọrin iyin
Bi harpu Dafidi didun.
f
Ọkàn mi o yọ̀ n’ Oluwa,
Y’ o yin iṣẹ at’ ọ̀rọ Rẹ̀
Iṣẹ ore Rè ti pọ̀ to!
Ijinlẹ sì ni ìmọ Re.
mf
Emi o yàn ipò ọla
‘Gb’ ore-ofẹ ba wẹ̀ mi nù
cr
Ti ayọ̀ pupọ̀ si a mi,
Ayọ̀ mimọ lat’ òke wá.
f
‘Gbana, ngo ri, ngo gbọ̀, ngo mọ̀
Ohun gbogbo ti mo ti nfẹ;
Lati ṣe ‘fẹ Rẹ titi lai. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites