Anglican Hymnal
All times and seasons, months and years
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 35: All times and seasons, months and years
Akoko odun at’ osu
Hymn:
35
Meter:
8.7.8.7
Season:
Ojo Oluwa
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Akoko ọdun at’ oṣu,
Gbogbo wọn l’Ọlọrun da;
Ojumọ ni fun ise wa,
Oru si ni lati sùn.
O si da ọjọ isimi;
N’nu ‘jọ meje, O mu ‘kan,
K’ enia ba le r’ aye ṣe
Ati sìn Ọlọrun wọn.
L’ọjọ mẹfa ni k’a ṣiṣẹ,
B’o ti yẹ ni ki a ṣe,
L’ ọjọ keje jẹ k’ a pejọ,
Ni ile Ọlọrun wa.
L’ ọjọ na yi a ngbadura,
A nkọrin didun sì I
A si nyin Ọlọrun l’ ogo,
T’ o ju ohun gbogbo lọ.
Nisisiyi kọrin iyìn,
T’Ọlọrun Oluwa wa:
ff
Kọrin didun, kọrin soke,
Ni yiyin Oluwa wa. Amin
« Back to Hymn List
View Favourites