Anglican Hymnal
This is the day the Lord hath made;
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 34: This is the day the Lord hath made;
Eyi l’ ojo t’ Oluwa da
Hymn:
34
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ojo Oluwa
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Eyi l’ ọjọ t’ Oluwa da,
O pe ‘gba na ntirẹ̀;
K’ orun k’ o yọ̀, k’ aiye k’ o yọ̀
K’ iyin yi ‘tẹ na ka.
Loni, o jinde ‘nu okù,
Ijọba Satan tu:
‘Won mimọ́ tan ṣẹgun Rẹ̀ ka
Nwọn nsọrọ ‘yanu Rẹ̀.
ff
Hosanna si Ọba t’ a yàn,
S’ Ọmọ mimọ́ Dafid’;
mf
Oluwa, jọ sọkalẹ wá
T’ Iwọ t’igbala Rẹ.
Abukun l’ Oluwa t’ o wá
N’iṣẹ ore-ọfẹ;
T’ o wá l’ orukọ Baba Rẹ̀,
Lati gba ‘ran wa là.
ff
Hosanna li ohun goro,
L’ orin Ijọ f’ aiye,
Orin t’ oke ọrun lọhun
Yio dùn jù bẹ lọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites