Anglican Hymnal
We sing the song thou love to hear
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 337: We sing the song thou love to hear
Awa ko orin ife Re
Hymn:
337
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ife si Olorun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Awa kọ orin ifẹ Rẹ,
Ọbangiji Ọba Ogo:
Kò s’ohun ti lalàṣi Rẹ,
Ọla Rẹ kò si nipẹkun.
f
N’nu ifẹ l’o ṣ’ẹda aiye,
O da enia sinu rẹ̀;
Lati ma ṣ’akoso gbogbo;
ff
Ẹ kọrin ‘fẹ Ẹlẹda wa.
f
Lojojumọ l’O ntọju wa,
O si mbọ́, O si nṣikẹ wa;
Bẹni mò gbà nkan lọwọ wa,
ff
Kọrin ‘yin s’onibu ọrẹ.
p
O ri wa ninu òkunkun,
Pe, a kò mọ̀ ojubọ rẹ̀;
N’ifẹ O fi ọna hàn wa;
ff
Ẹ kọrin ifẹ Olore!
N’ ifẹ O fi Jesu fun wa,
Ọmọbibi Rẹ̀ kanṣoṣo;
p
O wa rà wa lọwọ ẹ̀ṣẹ;
ff
A yin ‘fẹ Rẹ Olugbala!
Ifẹ Rẹ̀ ran ọ̀rọ Rẹ̀ wá,
Ifẹ Rẹ̀ l’o ṣi wa leti,
Ifẹ Rẹ sì mu wa duro;
ff
Ẹ kọrin ore-ọfẹ Rẹ̀.
Gbogbo ẹda kun fun ‘fẹ Rẹ,
Oluwa wa, Ọba aiye;
ff
Gbogbo agbaiye, ẹ gberin,
Orin ifẹ Ọlọrun wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites