Anglican Hymnal
When this passing world is done
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 336: When this passing world is done
’Gbat aiye yi ba koja
Hymn:
336
Meter:
7.7.7.7.7.7
Season:
Ife si Olorun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
‘Gbat aiye yi ba kọja,
Ti orùn rẹ̀ ba si wọ̀,
Ti a ba wọ̀ ‘nu ogo,
T’ a bojuwò ẹ̀hin wa;
f
‘Gbana, Oluwa, ngo mọ;
di
Bi gbese mi ti pọ̀ to.
f
‘Gba mo ba de ‘b’ itẹ Rẹ,
L’ẹwà ti kì ṣe t’emi;
‘Gba mo ri Ọ b’o ti ri,
Ti mo fẹ Ọ l’ afẹtan;
‘Gbana Oluwa, ngo mọ̀
di
Bi gbese mi ti pọ to.
f
‘Gba mba ngbọ́ orin ọrun,
Ti ndún bi ohùn ará,
Bi iró omi pupo:
p
T’ o si ndún b’ ohùn dùru;
mf
‘Gbana Oluwa, ngo mọ̀
di
Bi gbese mi ti pọ to.
mp
Oluwa, jọ, jẹ k’a ri
Ojiji Rẹ l’aiye yi:
p
K’a mọ̀ adùn dariji,
Pẹlu iranwọ Ẹmi:
cr
Ki ntilẹ̀ mọ̀ l’aiye yi,
Diẹ ninu gbèse mi.
mf
Ore-ọfẹ l’ o yàn mi,
L’ o yọ mi ninu ewu;
p
Jesu l’Olugbala mi,
Ẹmi sọ mi di mimọ́,
cr
Kọ mi, ki nfi hàn l’aiye,
Bi gbese mi ti pọ to ! Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites