Anglican Hymnal
There is a name I love to hear
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 334: There is a name I love to hear
Oruko kan mbe ti mo fe
Hymn:
334
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ife si Olorun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Orukọ kan mbẹ ti mo fẹ
Mo fẹ ma kọrin rẹ̀;
Iró didun ni l’eti mi,
Orukọ didun ni.
O sọ ifẹ Olugbala,
p
T’o kú lati rà mi;
O sọ t’ẹjẹ Rẹ̀ ‘yebiye
Etutu f’ ẹlẹṣẹ.
cr
O sọ ti iyọ́nu Baba,
Ti o ni s’ Ọmọ Rẹ̀;
O m’ ara mi yá, lati la
Aginjui aiye ja.
mf
Jesu, Orukọ ti mo fẹ,
T’o si dùn l’eti mi;
Kò s’ ẹni mimọ́ kan l’ aiye,
T’o mọ̀ b’ o ti pọ̀ to.
cr
Orukọ yi j’orùn didùn,
L’ọnà egún t’ a nrìn;
Yio tun ọnà yangi ṣe,
T’o lọ s’ọd’ Ọlọrun.
f
Nibẹ pẹlu awọn mimọ́,
Ti nwọn bọ́ nin’ ẹṣẹ,
Emi o kọrin titun ni,
T’ifẹ Jesu si mi. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites