Anglican Hymnal
My blessed Saviour, is Thy love
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 332: My blessed Saviour, is Thy love
Olugbala mi, ife Re
Hymn:
332
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ife si Olorun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Olugbala mi, ifẹ Rẹ
Ha tobi bẹ si mi?
Wo, mo f’ ifẹ mi, ọkàn mi,
At’ aiya mi fun Ọ.
Mo fẹ Ọ nitori ‘toye,
Ti mo ri ninu Rẹ;
p
Mo fẹ Ọ nitori ìya,
T’ o f’ ara dà fun mi.
f
Bi Iwọ ti jẹ Ọlọrun,
T’ a f’ ogo de l’ ade;
di
Iwọ kò kọ̀ àwọ enia,
T’ o kun fun iyọnu.
p
‘Wọ jẹ k’ a bi Ọ l’ enia,
Ṣugbọn ‘Wọ kò l’ẹ̀ṣẹ;
cr
K’ awa lè ri b’ Iwọ ti ri,
K’ a lè ṣe b’ O ti ṣe.
f
K’ a dabi Rẹ ninu ifẹ,
L’ ẹwà ìwa mimọ́;
cr
B’ a ti nwoju Rẹ, k’ a ma lọ,
L’ at’ ogo de ogo. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites