Anglican Hymnal
Jesus, the very thought of thee
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 330: Jesus, the very thought of thee
Jesu, kiki ironu Re
Hymn:
330
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ife si Olorun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Jesu, kìki ironu Rẹ,
Fi ayọ̀ kún ọkàn;
Ṣugbọn k’a ri Ọ l’o dùn jù,
K’a simi lọdọ Rẹ.
f
Ẹnu kò sọ, eti kò gbọ,
Ko ti ọkàn wá ri;
Okọ t’o sọ̀wọn, t’o dun bi
Ti Jesu Oluwa.
p
Ireti ọkàn ti nkanu,
Olore ẹlẹṣẹ;
cr
O ṣeun f’ awọn ti nwa Ọ,
f
Awọn t’o ri Ọ yọ̀.
f
Ayọ̀ wọn, ẹnu kò le sọ,
Ẹda kò le rohin;
Ifẹ Jesu, b’o ti pọ̀ to,
Awọn Tirẹ̀ l’o mọ̀.
f
Jesu, ‘Wọ ma jẹ ayọ̀ wa,
‘Wọ sa ni ère wa;
Ma jẹ ogo wa nisiyi,
Ati titi lailai. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites