Anglican Hymnal
Thine forever! God of love
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 324: Thine forever! God of love
Tire lailai l’ awa se
Hymn:
324
Meter:
7.7.7.7
Season:
Igbagbo
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Tirẹ lailai l’ awa ṣe,
Baba, Ọlọrun ifẹ;
cr
Jẹ ka jẹ Tirẹ titi,
Laiye yi, ati lailai.
f
Tirẹ lailai l’ awa ṣe,
Ma tọju wa l’ aiye yi:
‘Wọ ìye, ọnà, otọ,
Tọ́ wa si ilu ọrun.
p
Tirẹ lailai; --- Abukun
L’ awọn t’ o ṣe ‘simi wọn!
cr
Olugbala, Ọrẹ wa,
Gba ‘jà wa jà de opin.
p
Tirẹ lailai: --- Jesu, pa
Awọn agútan Rẹ mọ,
cr
Labẹ ìṣọ rere Rẹ
Ni k’o pa gbogbo wa mọ.
f
Tirẹ lailai:--- Aina awa
Ni o jẹ aniyàn Rẹ;
O ti f’ ẹ̀ṣẹ wa ji wa,
Tọ́ wa si ibugbe Rẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites