Anglican Hymnal
The King of love my shepherd is,
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 305: The King of love my shepherd is,
Jesu l’ Olusagutan mi
Hymn:
305
Meter:
8.7.8.7
Season:
Igbagbo
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Jesu l’Oluṣagutan mi,
Ore ẹniti ki yẹ̀!
Kò s’ewu bi mo jẹ Tirẹ̀,
T’ On sì jẹ temi titi.
f
Nib’ odo omi ìye nṣàn,
Nibẹ l’o nm’ ọkàn mi lọ;
Nibiti oko tutù nhù,
L’o nf’onjẹ ọrun bọ́ mi.
p
Mo ti fi wère ṣako lọ,
cr
B’ Iwọ ba wà lọdọ mi;
di
Ọgọ Rẹ ati ọpa Rẹ,
f
Awọn l’o ntù mi ninu.
p
Nkò bẹru ojiji iku,
cr
B’ Iwọ ba wà lọdọ mi;
Ọgọ Rẹ ati ọpa Rẹ,
Awọn l’o ntù mi ninu.
mf
Iwọ tẹ̀ tabili fun mi;
Wọ d’ ororo sori mi;
A ! ayọ̀ na ha ti pọ̀ to !
Ti nt’ ọdọ Rẹ wá ba mi.
f
Bẹ, lọjọ aiye mi gbogbo,
Ore Rẹ ki o yẹ̀ lai;
Oluṣagutan, ngo yìn Ọ,
Ninu ile Rẹ titi. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites